Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 7:21-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ se rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi.

22. Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run;

23. mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi.

24. Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara ikú yìí?

25. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa!Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnraà mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Róòmù 7