Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 7:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

15. Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń se. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ se gan an n kò se é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kóríra ni mo ń se.

16. Ṣùgbọ́n bí mo bá se ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára.

17. Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ se rí yìí kì í se èmi ni ó se é bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.

18. Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ mi. Èmi fẹ́ se èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe.

19. Níorí ohun tí èmi se kì í se ohun rere tí èmi fẹ́ láti se; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, éyí nì ni èmi ń se.

20. Nísinsin yìí, bí mo bá ń se nǹkan tí n kò fẹ́ láti se, kì í se ẹ̀mi fúnra mi ni ó se é, bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó se é.

21. Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ se rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi.

22. Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run;

23. mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi.

Ka pipe ipin Róòmù 7