Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 3:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Gbogbo wọn ni ó ti yapa,wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;kò sí ẹni tí ń ṣe rere,kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

13. “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní Ọ̀fun wọn:ahọ́n wọn di aláìlérè; kò sí ẹni ìtànjẹ.”“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

14. “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

15. “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:

16. Ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

17. Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”

18. “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

Ka pipe ipin Róòmù 3