Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 2:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀:

7. Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àínìpẹ̀kun fún.

8. Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń ẹ̀lé búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrúnú àti ìbínú rẹ̀.

9. Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú;

10. ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú:

11. Nítorí Olúwa kìí ṣe ojú ìsáájú ènìyàn.

12. Gbogbo àwọn tí ó sẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dálẹ́jọ́;

13. Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni aláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dáláre.

14. Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà àdánidá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin.

15. Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsìnyí.

16. Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jésù Kírísítì ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi.

17. Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálò rẹ̀ sí Ọlọ́run,

Ka pipe ipin Róòmù 2