Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 16:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í se èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ní ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.

5. Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń pé jọ fún pọ̀ ní ilé wọn.Ẹ kí Épénétù ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kírísítẹ́nì ní orílẹ̀ èdè Ésìà.

6. Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun fún yin.

7. Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi.

8. Ẹ kí Áńpílíátúsì, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.

9. Ẹ kí Úbánúsì, alábásisẹ́ pọ̀ wa nínú Kírísítì àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Sítákì.

10. Ẹ kí Ápẹ́lẹ́sì, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kírísítì.Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Árísítóbúlúsì.

11. Ẹ kí Héródíónì, ìbátan mi.Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Nákísísù tí wọ́n wá nínú Olúwa.

12. Ẹ kí Tírífẹ́nà àti Tírífósà, àwọn obìrin tí wọ́n se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.Ẹ kí Pásísì ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.

13. Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀pú.

14. Ẹ kí Ásínkírítúsì, Fílégónì, Hérímésì, Pátíróbà, Hérímásì àti àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.

15. Ẹ kí Fílólóhù, àti Júlíà, Néréù, àti arábìnrin rẹ̀, àti Ólíḿpà, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.

16. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.Gbogbo ìjọ kírísitì kí yín.

17. Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn.

Ka pipe ipin Róòmù 16