Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 16:19-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nítorí ìgbọ́ràn yín tàn kálẹ̀ dé ibi gbogbo., nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.

20. Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Sátanì mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.

21. Tìmótíù alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lúkíúsì, àti Jásónì, àti Sósípátérù, àwọn ìbátan mi, kí yín.

22. Èmi Térítíù tí ń kọ Èpísítélì yí, kí yín nínú Olúwa.

23. Gáíúsì, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó se náà fi ìkíni ránsẹ́.Érásítù, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó isẹ́ ìlú, àti arákùnrin wa Kúárítù fi ìkíni wọn ránsẹ́.

24. Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.

25. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹṣẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìn rere mi àti ìpolongo Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìsípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,

26. ṣùgbọ́n, nísinsinyí, a ti fihàn, a sì ti sọ ọ́ di mímọ̀ nípa àkọsílẹ̀ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbàgbọ́, kí wọn sì le se ìgbọ́ràn sí i pẹ̀lú;

27. kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnì kan ṣoṣo tí ọgbọ́n í se tirẹ̀ nípa Jésù Kírísítì! Àmín.

Ka pipe ipin Róòmù 16