Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 16:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kírísítì Olúwa wa, bí kò se ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ geere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà.

19. Nítorí ìgbọ́ràn yín tàn kálẹ̀ dé ibi gbogbo., nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.

20. Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Sátanì mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.

21. Tìmótíù alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lúkíúsì, àti Jásónì, àti Sósípátérù, àwọn ìbátan mi, kí yín.

22. Èmi Térítíù tí ń kọ Èpísítélì yí, kí yín nínú Olúwa.

23. Gáíúsì, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó se náà fi ìkíni ránsẹ́.Érásítù, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó isẹ́ ìlú, àti arákùnrin wa Kúárítù fi ìkíni wọn ránsẹ́.

24. Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.

25. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹṣẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìn rere mi àti ìpolongo Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìsípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,

26. ṣùgbọ́n, nísinsinyí, a ti fihàn, a sì ti sọ ọ́ di mímọ̀ nípa àkọsílẹ̀ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbàgbọ́, kí wọn sì le se ìgbọ́ràn sí i pẹ̀lú;

27. kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnì kan ṣoṣo tí ọgbọ́n í se tirẹ̀ nípa Jésù Kírísítì! Àmín.

Ka pipe ipin Róòmù 16