Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 16:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo fi Fébè arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díaókọ́nì nínú ìjọ tí ó wà ní Kéńkíríà.

2. Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ẹ̀nìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.

3. Ẹ kí Pìrìsílà àti Àkúílà, àwọn tí ó ti jẹ́ alábásiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kírísítì Jésù.

4. Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í se èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ní ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.

5. Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń pé jọ fún pọ̀ ní ilé wọn.Ẹ kí Épénétù ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kírísítẹ́nì ní orílẹ̀ èdè Ésìà.

6. Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun fún yin.

7. Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi.

Ka pipe ipin Róòmù 16