Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 16:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo fi Fébè arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díaókọ́nì nínú ìjọ tí ó wà ní Kéńkíríà.

2. Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ẹ̀nìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.

3. Ẹ kí Pìrìsílà àti Àkúílà, àwọn tí ó ti jẹ́ alábásiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kírísítì Jésù.

4. Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í se èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ní ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.

5. Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń pé jọ fún pọ̀ ní ilé wọn.Ẹ kí Épénétù ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kírísítẹ́nì ní orílẹ̀ èdè Ésìà.

6. Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun fún yin.

7. Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi.

8. Ẹ kí Áńpílíátúsì, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.

9. Ẹ kí Úbánúsì, alábásisẹ́ pọ̀ wa nínú Kírísítì àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Sítákì.

10. Ẹ kí Ápẹ́lẹ́sì, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kírísítì.Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Árísítóbúlúsì.

11. Ẹ kí Héródíónì, ìbátan mi.Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Nákísísù tí wọ́n wá nínú Olúwa.

Ka pipe ipin Róòmù 16