Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 14:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àwọn kan bu ọlá fún ju ọ̀kan lọ, ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú nípa èyí tí ó tọ́ lọ́kàn ara rẹ̀.

6. Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.

7. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀.

8. Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, yálà ní kíkú tàbí ní yíyè, ti Olúwa ni àwá jẹ́.

9. Nítorí ìdí èyí náà ni Kírísítì fi kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààye.

Ka pipe ipin Róòmù 14