Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 14:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má se tọpinpin ìṣiyèméjì rẹ̀.

2. Ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fi ààyè gbà á láti jẹ ohun gbogbo: sùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan.

3. Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi: nítorí Ọlọ́run ti gbà á.

4. Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ tí kì í se tìrẹ lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun ni dúró, tàbí subú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.

5. Àwọn kan bu ọlá fún ju ọ̀kan lọ, ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú nípa èyí tí ó tọ́ lọ́kàn ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Róòmù 14