Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 12:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Níti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa.

12. Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gangan nínú àdúrà.

13. Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò íṣe.

14. Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè.

15. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ má bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkùn, ẹ má bá wọn sọkún.

16. Ẹ má wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe ronú ohun gíga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.

17. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn.

18. Bí ó le ṣe, bí ó ti wà ní ipa ti yín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.

19. Olùfẹ́, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Èmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.”

20. Ṣùgbọ́n bí ebi bá ń pa ọ̀ta rẹ:“Fún un ní oúnjẹ; bí oùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́,fún un ní omi mu;ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”

21. Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.

Ka pipe ipin Róòmù 12