Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 12:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́-ìsìn yín tí ó tọ̀nà.

2. Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di titun ní ìrò-inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.

3. Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ̀ntún-wọ̀nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olukúkùlù.

4. Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà pípọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà:

5. Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ pípọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kírísítì, àti olukúlùkú ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀.

6. Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀-ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí ore-ọ̀fẹ́ tí a fifún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́;

7. Tàbí iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí a kọjúsí iṣẹ́-ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́.

8. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń sàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.

9. Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takéte sí ohun tí í ṣe búrubú; ẹ faramọ́ ohun tí í ṣe rere.

10. Níti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkéjì yín ṣájú.

11. Níti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa.

12. Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gangan nínú àdúrà.

13. Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò íṣe.

14. Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè.

Ka pipe ipin Róòmù 12