Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 1:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì ẹni tí a ti pè láti jẹ́ Àpósítélì, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìyìnrere Ọlọ́run.

2. Ìyìnrere tí a ti pinnu láti ẹnu àwọn wòlíì nínú ìwé Mímọ́ láti ìgbà pípẹ́ ṣáájú ìsinsin yìí.

3. Nípa ìfiyèsí ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ ìran Dáfídì nípa ìbí ti ènìyàn.

4. Ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹmi ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jésù Kírísítì Olúwa wa.

5. Láti ọdọ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ Àpósítélì gbà, láti wàásù fún gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè kí wọn kí ó lè wá sínú ìgbàgbọ́ èyíni ní orúkọ rẹ̀.

6. Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jésù Kírísítì.

7. Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Róòmù tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́:Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

8. Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Jésù kírísítì fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.

Ka pipe ipin Róòmù 1