1. Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá.
2. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn wí pé:
3. “Alábùkún-fún ni àwọn òtòsì ní ẹ̀mí,nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
4. Alábùkún-fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,nítorí a ó tù wọ́n nínú.
5. Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,nítorí wọn yóò jogún ayé.
6. Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń patí òùngbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
7. Alábùkún-fún ni àwọn aláàánú,nítorí wọn yóò rí àánú gbà.
8. Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.
9. Alábùkún-fún ni àwọn tonílàjà,nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.