Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 5:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá.

2. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn wí pé:

3. “Alábùkún-fún ni àwọn òtòsì ní ẹ̀mí,nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

4. Alábùkún-fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,nítorí a ó tù wọ́n nínú.

5. Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,nítorí wọn yóò jogún ayé.

Ka pipe ipin Mátíù 5