Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 4:8-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo orílẹ̀-èdè ayé àti gbogbo ẹwà wọn hàn án.

9. Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

10. Jésù wí fún un pé, “Kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, ìwọ Sàtánì! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ ó sìn.’ ”

11. Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì sì tọ̀ ọ́ wá láti jísẹ́ fún un.

12. Nígbà tí Jésù gbọ wí pé a ti fi Jòhánù sínu túbú ó padà sí Gálílì.

13. Ó kúrò ní Násárẹ́tì, ó sì lọ ígbé Kápánámù, èyí tí ó wà létí òkun Sébúlónì àti Náfítálì.

14. Kí èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:

15. “Iwọ Sébúlónì àti ilẹ̀ Náfítalìọ̀nà tó lọ sí òkun, ní ọ̀nà Jọ́dánì,Gálílì ti àwọn aláìkọlà,

16. Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùntí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikuni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

17. Láti ìgbà náà lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

18. Bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Símónì, ti à ń pè ní Pétérù, àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń ju sọ àwọn wọn sínú òkun nítorí apẹja ni wọ́n.

19. Jésù wi fun wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”

Ka pipe ipin Mátíù 4