10. Jésù wí fún un pé, “Kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, ìwọ Sàtánì! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ ó sìn.’ ”
11. Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì sì tọ̀ ọ́ wá láti jísẹ́ fún un.
12. Nígbà tí Jésù gbọ wí pé a ti fi Jòhánù sínu túbú ó padà sí Gálílì.
13. Ó kúrò ní Násárẹ́tì, ó sì lọ ígbé Kápánámù, èyí tí ó wà létí òkun Sébúlónì àti Náfítálì.
14. Kí èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:
15. “Iwọ Sébúlónì àti ilẹ̀ Náfítalìọ̀nà tó lọ sí òkun, ní ọ̀nà Jọ́dánì,Gálílì ti àwọn aláìkọlà,
16. Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùntí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikuni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”
17. Láti ìgbà náà lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”