Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 28:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Máríà Magidalénì àti Màríà kejì lọ sí ibojì.

2. Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí ańgẹ́lì Olúwa ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí.

3. Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

4. Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wá rìrì wọn sì dàbí òkú.

5. Nígbà náà ni ańgẹ́lì náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jésù tí a kàn mọ́ àgbélébùú.

6. Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí.

7. Nísinsìn yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Gálílì síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóògbé rí i, wò ó, o ti sọ fún yin”.

8. Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìróyìn tí ańgẹ́lì náà fi fún wọn.

Ka pipe ipin Mátíù 28