Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 28:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Máríà Magidalénì àti Màríà kejì lọ sí ibojì.

2. Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí ańgẹ́lì Olúwa ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí.

3. Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

Ka pipe ipin Mátíù 28