Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:50-66 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

50. Nígbà tí Jésù sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.

51. Lójú kan náà aṣọ ìkélé tẹ̀ḿpìlì fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán.

52. Àwọn isà òkú sì sí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn olódodo ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti kú sì tún jíǹde.

53. Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jésù, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.

54. Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ Jésù rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í sẹ!”

55. Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Gálílì pẹ̀lú Jésù láti tọ́jú Rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè.

56. Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Màríà Magidalénì, àti Màríà ìyá Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, àti ìyá àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

57. Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatíyà, tí à ń pè ní Jósẹ́fù, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù,

58. lọ sọ́dọ̀ Pílátù, ó sì tọrọ òkú Jésù. Pílátù sì pàṣẹ kí a gbé é fún un.

59. Jósẹ́fù sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í.

60. Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnraa rẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ.

61. Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wà níbẹ̀, wọn jòkóò dojú kọ ibojì náà.

62. Lọjọ́ kejì tí ó tẹlé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ sọ́dọ̀ Pílátù.

63. Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, ẹlẹ́tàn náà wí nígbà kan pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’

64. Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọn-ingbọn-in títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ má ṣe wá jí i gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”

65. Pílátù sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.”

66. Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáadáa. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.

Ka pipe ipin Mátíù 27