Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:5-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà náà ni Júdásì da owó náà sílẹ̀ nínú tẹ̀ḿpìlì. Ó jáde, ó sì lọ pokùnṣo.

6. Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí pẹ̀lú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.”

7. Nítorí náà wọ́n pínnú, láti fi owó náà ra ilẹ̀ kan, níbi tí àwọn amọ̀kòkò ti ń rí amọ̀ wọn, àti láti lo ilẹ̀ náà fún ìsìnkú fún àwọn àlejò tí ó bá kú ní Jerúsálémù.

8. Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ìlẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní.

9. Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremáyà wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Ísírẹ̀lì díye lé e.

10. Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”

11. Nígbà náà ni Jésù dúró níwájú Baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni Ọba àwọn Júù?”Jésù dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”

12. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfàà àti àwọn àgbààgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jésù kò dáhùn kan.

13. Nígbà náà ni Pílátù, béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?”

14. Jésù kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya Baálẹ̀ lẹ́nu.

15. Ó jẹ́ àṣà Baálẹ̀ láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni.

16. Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Bárábbà.

Ka pipe ipin Mátíù 27