Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:32-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kíréné tí à ń pè ní Símónì. Wọ́n sì mú ọkùnn náà ní túlààsì láti ru àgbélébùú Jésù.

33. Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọ́lígọ́tà, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.)

34. Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún.

35. Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn.

36. Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀.

37. Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé: “ÈYÍ NI JÉSÙ, ỌBA ÀWỌN JÚÙ” síbẹ̀.

38. Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀.

39. Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé:

40. “Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ-Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀ kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”

Ka pipe ipin Mátíù 27