Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí Júdásì, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù.

4. Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”

5. Nígbà náà ni Júdásì da owó náà sílẹ̀ nínú tẹ̀ḿpìlì. Ó jáde, ó sì lọ pokùnṣo.

6. Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí pẹ̀lú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.”

7. Nítorí náà wọ́n pínnú, láti fi owó náà ra ilẹ̀ kan, níbi tí àwọn amọ̀kòkò ti ń rí amọ̀ wọn, àti láti lo ilẹ̀ náà fún ìsìnkú fún àwọn àlejò tí ó bá kú ní Jerúsálémù.

8. Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ìlẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní.

Ka pipe ipin Mátíù 27