Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:21-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà tí baálẹ́ sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Bárábbà!”

22. Pílátù béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jésù ẹni ti a ń pè ní Kírísítì?”Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

23. Pílátù sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

24. Nígbà tí Pílátù sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnraa yín, ẹ bojú tó o!”

25. Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!”

Ka pipe ipin Mátíù 27