Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:13-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà náà ni Pílátù, béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?”

14. Jésù kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya Baálẹ̀ lẹ́nu.

15. Ó jẹ́ àṣà Baálẹ̀ láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni.

16. Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Bárábbà.

17. Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti pé jọ ṣíwájú ilé Pílátù lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Bárábbà tàbí Jésù, ẹni tí ń jẹ́ Kírísítì?”

18. Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́,;

19. Bí Pílátù sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.”

20. Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Bárábà sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jésù.

21. Nígbà tí baálẹ́ sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Bárábbà!”

22. Pílátù béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jésù ẹni ti a ń pè ní Kírísítì?”Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

23. Pílátù sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

Ka pipe ipin Mátíù 27