Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 27:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tún padà láti gbìmọ bí wọn yóò ti ṣe pa Jésù.

2. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pílátù tí i ṣe gómìnà.

3. Nígbà tí Júdásì, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù.

4. Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”

5. Nígbà náà ni Júdásì da owó náà sílẹ̀ nínú tẹ̀ḿpìlì. Ó jáde, ó sì lọ pokùnṣo.

6. Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí pẹ̀lú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.”

7. Nítorí náà wọ́n pínnú, láti fi owó náà ra ilẹ̀ kan, níbi tí àwọn amọ̀kòkò ti ń rí amọ̀ wọn, àti láti lo ilẹ̀ náà fún ìsìnkú fún àwọn àlejò tí ó bá kú ní Jerúsálémù.

8. Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ìlẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní.

9. Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremáyà wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Ísírẹ̀lì díye lé e.

Ka pipe ipin Mátíù 27