Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 26:59-61 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

59. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù pé jọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jésù, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un.

60. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde.

61. Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘èmi lágbára láti wó tẹ̀ḿpìlì Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”

Ka pipe ipin Mátíù 26