Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 26:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jésù pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.

5. Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”

6. Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Símónì adẹ́tẹ̀;

7. Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgò òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.

8. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yin rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí?

9. È é ha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”

10. Jésù ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi

11. Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrin yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Mátíù 26