Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 26:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

2. “Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ-Ènìyàn lé ni lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”

3. Ní àsìkò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfàá àti àwọn àgbààgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfàá náà tí à ń pè ní Káíáfà.

4. Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jésù pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.

5. Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”

6. Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Símónì adẹ́tẹ̀;

Ka pipe ipin Mátíù 26