Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 25:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’

21. “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́: ìwọ ṣe olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

22. “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ńtì méjì mìíràn.’

23. “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

24. “Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé oǹrorò enìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kó jọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí.

25. Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ńtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí.’

26. “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kó jọ níbi tí èmi kò ó ká sí.

27. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè.

Ka pipe ipin Mátíù 25