Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 25:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “Nítorí náà, Ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ-Ènìyàn yóò dé.

14. “A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìn-àjò. Ó pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn.

15. Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ntì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ntì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìn-àjò tirẹ̀.

16. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi owó náà ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè márùn-ún mìíràn.

17. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè talẹ́ntì méjì mìíràn.

18. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀.

19. “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀. Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn sírò owó rẹ̀.

20. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’

21. “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́: ìwọ ṣe olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

Ka pipe ipin Mátíù 25