Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 24:41-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ́ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹnì kejì sílẹ̀.

42. “Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé.

43. Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀.

44. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúra-sílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ-Eènìyàn yóò jẹ́.

45. “Ǹjẹ́ olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́?

46. Alábùkún fún ni ọmọ-ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe.

47. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní.

48. Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú, tí ó sì ń wí fún ara rẹ̀ pé, ‘olúwa mi kì yóò tètè dé.’

49. Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara.

50. Nígbà náà ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò rétí.

51. Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ìdájọ́ àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.

Ka pipe ipin Mátíù 24