Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 24:33-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadabọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

34. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.

35. Ọ̀run àti ayé yóò ré kọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò ré kọjá.

36. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn ańgẹ́lì pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ Ọlọ́run kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n.

37. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Nóà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn yóò sì rí.

38. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Nóà fi bọ́ sínú ọkọ̀.

39. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn.

40. Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a yóò mú ẹnì kan, a ó sì fi ẹnì kejì sílẹ̀.

41. Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ́ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹnì kejì sílẹ̀.

42. “Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé.

43. Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀.

44. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúra-sílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ-Eènìyàn yóò jẹ́.

45. “Ǹjẹ́ olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́?

46. Alábùkún fún ni ọmọ-ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe.

47. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní.

48. Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú, tí ó sì ń wí fún ara rẹ̀ pé, ‘olúwa mi kì yóò tètè dé.’

49. Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara.

50. Nígbà náà ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò rétí.

Ka pipe ipin Mátíù 24