Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 24:3-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Bí ó ti jókòó ní orí òkè Ólífì, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní kọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ àmì ìpadàwá rẹ, àti ti òpin ayé?”

4. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ.

5. Nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ní orúkọ mi tí wọn yóò máa pe ara wọn ní Kírísítì náà. Wọn yóò ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà.

6. Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má se jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà.

7. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn àti ilẹ̀ mímì yóò wà ní ibi púpọ̀.

8. Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ó ń bọ̀.

9. “Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo ayé, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi.

10. Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú,

11. ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì èké yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ.

12. Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù,

13. ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbà là.

14. A ó sì wàásù ìyìn rere nípa ìjọba náà yí gbogbo ayé ká, kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ, nígbà náà ni òpin yóò dé ní ìkẹyìn.

15. “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìṣọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e).

16. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Jùdíà sá lọ sí àwọn orí òkè.

17. Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀ kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.

18. Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn.

19. Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì!

20. Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi.

Ka pipe ipin Mátíù 24