Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 23:24-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ẹ̀yin afọ́jú tó ń afójú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ràkúnmí mì.

25. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisí àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde aago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo.

26. Ìwọ afọ́jú Farisí, tètè kọ́ fọ inú aago àti àwo, gbogbo aago náà yóò sì di mímọ́.

27. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisí àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì fúnfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́.

28. Ẹ̀yin gbìyànjú láti fara hàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yínni ọkàn tí ò kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.

29. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tíí ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀sọ́.

30. Ẹ̀yin sì wí pé, Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì.

31. Ǹjẹ́ ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí fún ara yín pé, ẹ̀yin ni ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wòlíì.

32. Àti pé, ẹ̀yin ń tẹ̀lé ìṣísẹ̀ àwọn baba yín. Ẹ̀yin ń kún òsùwọ̀n ìwà búburú wọn dé òkè.

33. “Ẹ̀yin ejò! Ẹ̀yin paramọ́lẹ̀! Ẹ̀yin yóò ti ṣe yọ nínú ẹbí ọ̀run àpáàdì?

34. Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú sínágọ́gù yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú.

35. Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ pa, láti ẹ̀jẹ̀ Ábélì títí dé ẹ̀jẹ̀ Ṣákaráyà ọmọ Berekáyà ẹni tí ẹ pa nínú Tẹ́ḿpìlì láàrin ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

36. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí.

37. “Jerúsálémù, Jerúsálémù, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adíyẹ̀ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀.

38. Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro.

Ka pipe ipin Mátíù 23