Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 23:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Àti pé, Ẹmikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò já mọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè.

19. Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀ jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnra rẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́?

20. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀.

21. Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹ́mńpílì búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀.

22. Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lóri rẹ̀ búra.

23. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá míńtì, áníṣè àti kùmínì, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe.

24. Ẹ̀yin afọ́jú tó ń afójú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ràkúnmí mì.

25. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisí àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde aago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo.

26. Ìwọ afọ́jú Farisí, tètè kọ́ fọ inú aago àti àwo, gbogbo aago náà yóò sì di mímọ́.

27. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisí àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì fúnfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́.

28. Ẹ̀yin gbìyànjú láti fara hàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yínni ọkàn tí ò kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.

29. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tíí ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀sọ́.

30. Ẹ̀yin sì wí pé, Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì.

31. Ǹjẹ́ ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí fún ara yín pé, ẹ̀yin ni ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wòlíì.

Ka pipe ipin Mátíù 23