Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 22:40-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”

41. Bí àwọn Farisí ti kó ara wọn jọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé,

42. “Kí ni ẹ rò nípa Kírísítì? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?”Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dáfídì.”

43. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni dé tí Dáfídì, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,

44. “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi,“Jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún mitítí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀ta rẹsí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’

45. Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun se lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

46. Kò sí ẹnì kan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.

Ka pipe ipin Mátíù 22