Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 22:34-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, àwọn Farisí pé ara wọn jọ.

35. Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí.

36. Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”

37. Jésù dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’

38. Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ.

Ka pipe ipin Mátíù 22