Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 22:24-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mósè wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ sú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un.

25. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrin wa níhìn-in yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú láìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì.

26. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títítí òun fi di ìyàwó ẹnì kéje.

27. Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú.

28. Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú?”

29. Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run.

30. Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn ańgẹ́lì ní ọ̀run.

31. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé:

32. ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”

33. Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ.

34. Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, àwọn Farisí pé ara wọn jọ.

35. Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí.

Ka pipe ipin Mátíù 22