Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 22:15-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà náà ni àwọn Farisí pé jọ pọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un.

16. Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hérọ́dù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olótìítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

17. Nísinsìn yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó-orí fún Késárì tàbí kò tọ́?”

18. Ṣùgbọ́n Jésù ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, è é se ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò?

19. Ẹ fi owo ẹyọ tí a fi ń san owo-orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un,

20. ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán tabi èyí? Àkọlé tà sì ní?”

21. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Késárì ni.”“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Késárì fún Késárì, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

22. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnú yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

23. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusí tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jésù wá láti bi í ní ìbéèrè pé,

24. Wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mósè wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ sú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un.

25. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrin wa níhìn-in yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú láìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì.

Ka pipe ipin Mátíù 22