Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 20:31-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sóke sí i. “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”

32. Jésù dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n pé, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”

33. Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.”

34. Àánú wọn sì ṣe Jésù, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójú kan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Ka pipe ipin Mátíù 20