Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 20:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jí jáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

2. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

3. “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.

4. Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’

5. Wọ́n sì lọ“Ó tún jáde lọ́sàn-án ní nǹkan bí wákàtí kẹfa àti wákàtí kẹṣàn-án, ó tún ṣe bákan náà.

6. Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárin ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘È é ṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’

7. “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’

8. “Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òsiṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’

9. “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnì kọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan.

10. Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣíṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó ti wọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan.

11. Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà,

12. Pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gan-gan.’

Ka pipe ipin Mátíù 20