Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 18:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. “Arákùnrin náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’

30. “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbésè náà tán pátápátá.

31. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀.

32. “Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ Ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbésè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi;.

33. Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣáànú fún ọ?’

34. Ní ibínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbésè èyí ti ó jẹ ẹ́.

35. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnì kọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”

Ka pipe ipin Mátíù 18