Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 18:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó tóbi jùlọ ní ìjọba ọ̀run?”

2. Jésù sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrin wọn.

3. Ó wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run.

4. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run.

Ka pipe ipin Mátíù 18