Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 17:7-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n Jésù sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

8. Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jésù nìkan ni wọn rí.

9. Bí wọ́n sì ti ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù pàṣẹ fún wọn pé “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí ọmọ-ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú”

10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Èlíjà ní láti kọ́ padà wá”

11. Jésù sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Èlíjà wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò.

12. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Èlíjà ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.”

13. Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Jòhánù onítẹ̀bọmi fún wọn ni.

14. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn,. ọkùnrin kan tọ̀ Jésù wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé,

15. “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubu sínú iná tàbí sínú omi.

16. Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.”

17. Jésù sì dáhùn wí pé, “A! ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.”

18. Nígbà náà ni Jésù bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ.

19. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jésù níkọ̀kọ̀ pé, “È é ṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”

20. Jésù sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòòtọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí músítadì, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Ṣípò kúrò níhìn-ín yìí’ òun yóò sì sí ipò. Kò sì nií sí ohun tí kò níí ṣe é ṣe fún yín.”

21. Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí èṣù yìí kò ní lọ, bí kò ṣe nípa ààwẹ̀ àti àdúrà.

Ka pipe ipin Mátíù 17