Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 17:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nígbà tí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kápánámù, àwọn agbowó-òde tọ Pétérù wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ Olúwa yín ń dá owó tẹ̀ḿpìlì?”

25. Pétérù sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.”Nígbà tí Pétérù wọ ilé láti bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jésù ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jésù bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Ǹjẹ́ àwọn ọba ń gba owó-orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?”

26. Pétérù dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.”Jésù sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó-òde?

27. ‘Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú’ Nítorí náà, ẹ lọ sí etí òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó-orí tèmi àti tirẹ̀.”

Ka pipe ipin Mátíù 17