Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 17:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jésù níkọ̀kọ̀ pé, “È é ṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”

20. Jésù sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòòtọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí músítadì, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Ṣípò kúrò níhìn-ín yìí’ òun yóò sì sí ipò. Kò sì nií sí ohun tí kò níí ṣe é ṣe fún yín.”

21. Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí èṣù yìí kò ní lọ, bí kò ṣe nípa ààwẹ̀ àti àdúrà.

22. Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Gálílì, Jésù sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.

23. Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹ́ta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi.

24. Nígbà tí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kápánámù, àwọn agbowó-òde tọ Pétérù wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ Olúwa yín ń dá owó tẹ̀ḿpìlì?”

25. Pétérù sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.”Nígbà tí Pétérù wọ ilé láti bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jésù ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jésù bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Ǹjẹ́ àwọn ọba ń gba owó-orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?”

26. Pétérù dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.”Jésù sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó-òde?

Ka pipe ipin Mátíù 17