Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 17:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dá dúró.

2. Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn; Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀.

3. Lójijì, Mósè àti Èlíjà fara hàn, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀.

4. Pétérù sọ fún Jésù pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà.”

5. Bí Pétérù ti sọ̀rọ̀ tán, àwọ̀sánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”

6. Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojú bolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

7. Ṣùgbọ́n Jésù sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

8. Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jésù nìkan ni wọn rí.

Ka pipe ipin Mátíù 17