Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀,’ ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ ofin di asan nípa àṣà yín.

7. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

8. “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

9. Lásán ni ìsìn wọn;nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyan kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

10. Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín.

11. Ènìyàn kò di ‘aláìmọ́’ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ni di ‘aláìmọ́.’ ”

12. Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisí lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ?” yìí

13. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fà tu ti gbòǹgbò ti gbòǹgbò,

14. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”

15. Pétérù wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”

16. Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èé ha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”?

Ka pipe ipin Mátíù 15